Yoruba Hymn: Ẹ jẹ ka jumọ f’ọpẹ f’Ọlọrun

Ẹ jẹ ka jumọ f’ọpẹ f’Ọlọrun

Orin iyin at’ọpẹ l’o yẹ wa,

Ìyanu n’ifẹ rẹ sí gbogbo wa,

Ẹ kọrin ‘yin sọba Olore wa.

 

Refrain:

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun

A f’ijo ilu yin Ọlọrun wa,

Alaye ni o yin Ọ b’otiyẹ,

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun.

 

 

Kil’a fi san j’awọn t’iku ti pa?

Iwọ l’O f’ọwọ wọ wa di oni

‘Wọ l’O nsọ wa t’o ngba wa l’ọw’ewu

Ẹ kọrin ‘yin s’olutoju wa.

 

Refrain:

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun

A f’ijo ilu yin Ọlọrun wa,

Alaye ni o yin Ọ b’otiyẹ,

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun.

 

 

Gbogbo alaye l’O nfun l’onjẹ wọn

Iwọ l’O pèsè f’onikaluku

‘Wọ l’O nsikẹ Ẹda Rẹ gbogbo

Ẹ kọrin ‘yin sí Onibu-ọrẹ

 

Refrain:

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun

A f’ijo ilu yin Ọlọrun wa,

Alaye ni o yin Ọ b’otiyẹ,

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun.

 

 

Ohun wa ko dun to lati kọrin

Ẹnu wa ko gbórò to fún ọpẹ,

B’awa n’ẹgbẹrun ahọn nikọkan

Nwọn kere ju lati gb’ọla Rẹ ga.

 

Refrain:

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun

A f’ijo ilu yin Ọlọrun wa,

Alaye ni o yin Ọ b’otiyẹ,

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun.

 

 

Gbe wa l’eke ‘soro l’ọjọ gbogbo

Fun wa layọ at’alafia Rẹ,

Jẹ k’a le s’eyit’o wu Ọ n’jọ gbogbo

K’a ba le wa f’ogo f’Orukọ Rẹ

 

Refrain:

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun

A f’ijo ilu yin Ọlọrun wa,

Alaye ni o yin Ọ b’otiyẹ,

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun.

 

 

Ẹny’n Angẹli l’Ọrun ba wa gbe

Orin iyin at’ọpẹ t’o yẹ wa,

S’Ọba wa Jèhófà ti o jọba

Ọba wa aiku Ọlọlajulọ

 

Refrain:

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun

A f’ijo ilu yin Ọlọrun wa,

Alaye ni o yin Ọ b’otiyẹ,

Halleluya! Ogo ni f’Ọlọrun.

 

Picturecredit: https://kwekudee-tripdownmemorylane.blogspot.com

 

 

 

 

Leave a Reply