Yoruba Hymn: Ẹ Yọ Nínú Olúwa, Ẹ Yọ – Be glad in the Lord, and rejoice

Yoruba Hymn: Ẹ Yọ Nínú Olúwa, Ẹ Yọ – Be glad in the Lord, and rejoice

Ẹ Yọ Nínú Olúwa, Ẹ Yọ – Mary E. Servoss

 

Ẹ yọ nínú Olúwa, ẹ yọ,

Ẹyin t’ọkan rẹ ṣe dede;

Ẹyin t’o ti yan Oluwa,

Le ‘banujẹ at’aro lọ.

 

 

Refrain:

Ẹ yọ! Ẹ yọ!

Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ!

Ẹ yọ! Ẹ yọ

Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ!

 

 

Ẹ yọ torí On l’Oluwa,

L’ayé ati l’órun pẹlu

Ọrọ Rẹ bor’ohun gbogbo,

O l’agbara lati gbala

 

 

‘Gbat’ ẹ ba nja ìjà réré,

Ti ọta fẹrẹ bori yin;

Ogun Ọlọrun t’ẹ ko ri

Pọ jù awọn ọta yin lọ.

 

 

B’okunkun tilẹ yi ọ ka,

Pẹlu iṣudẹdẹ gbogbo,

Maṣe jẹ k’ọkan rẹ da’mu,

Sa gbẹkẹl’Oluwa, d’opin.

 

 

Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ,

Ẹ kọrin iyin Rẹ kikan;

Fi dùru ati ohun kọ

Halleluyah l’ohun goro.

 

 

English Version

 

Be glad in the Lord, and rejoice,
All ye that are upright in heart;
And ye that have made Him your choice,
Bid sadness and sorrow depart.

 

Refrain:
Rejoice, rejoice,
Be glad in the Lord and rejoice;
Rejoice, rejoice,
Be glad in the Lord and rejoice.

 

Be joyful, for He is the Lord
On earth and in Heaven supreme;
He fashions and rules by His word—
The “Mighty” and “Strong” to redeem.

 

 

What though in the conflict for right
Your enemies almost prevail?
God’s armies, just hid from your sight,
Are more than the foes which assail.

 

Though darkness surround you by day,
Your sky by the night be o’ercast,
Let nothing your spirit dismay,
But trust till the danger is past.

 

Be glad in the Lord, and rejoice,
His praises proclaiming in song;
Let gratefulness give all a voice,
The loud hallelujahs prolong!

Leave a Reply