Yoruba Hymn: Ninu Gbogbo Ewu Oru

Yoruba Hymn: Ninu Gbogbo Ewu Oru

Ninu Gbogbo Ewu Oru

Hymn no.14 of the Christ Apostolic Church Hymn Book

 

  1. Ninu gbogbo ewu oru,

         Oluwa l’o sọ mi;

         Àwa sì tún rí ‘mọlẹ yi

         A tun tẹ ekun ba.

 

  1. Oluwa, pa wa mọ l’oni,

         Fi apa Rẹ sọ wa;

         Kiki awọn ti’wọ pamọ,

         L’o nyọ ninu ewu. 

 

  1.  K’ọrọ wa, ati iwa wa

          Wipe, tirẹ l’awa;

          Tobẹ t’imọlẹ otitọ

          Le tan l’oju ayé. 

 

  1. Ma jẹ k’apada lọdọ Rẹ

         Olugbala ọwọn;

         Titi ao f’ojú wa ri

         Oju Rẹ li opin. Amin

 

Leave a Reply