Yoruba Hymn: Nigbakan ni Bethelemu – Once in royal David’s city

 1. Nigbakan ni Bethelemu
  Ile kekere kan wà.
  Nibi’iya kan tẹ’mọ rẹ sí
  Lori Ibujẹ ẹran;
  Maria n’iya ọmọ na
  Jésù Kristi l’ọmọ na.
 2. O t’ọrun wa sode aiye
  On L’Ọlọrun Oluwa
  O f’ile ẹran ṣe ile
  Bujẹ ẹran fun ‘busun
  Lọ dọ awọn òtòṣì
  Ni Jesu gbe li aiye.
 3. Ni gbogbo igba ewe rẹ,
  O ngbọran o si mb’ọla,
  O fẹràn o si ntẹriba
  Fun Iya ti ntọjú rẹ,
  O yẹ ki gbogbo ọmọdé
  K’ó ṣe olugbọran bẹ
 4. Tori on jẹ awoṣe wa
  A ma dagba bi awa
  O kere ko le da nkan se
  A ma sọkún bi awa
  O sí le bawa daro
  O le ba wa yọ pẹlu
 5. A o f’ojú wa ri nikẹhin
  Ni agbara ìfẹ rẹ
  Nitori Ọmọ rere yi
  Ni Oluwa wa l’ọdun
  O ntọ awa ọmọ Rẹ
  S’ọna ibiti On lọ,
 6. Kiṣẹ ni ibujẹ ẹran
  Nibiti malu njẹun
  L’awa ori ṣugbọn l’ọrun
  L’ọwọ ọtun Ọlọrun
  ‘Gba wọn’mọ Rẹ b’irawọ
  Ba wa n’nu aṣọ ala. Amin.

English Version

 1. Once in royal David’s city
  Stood a lowly cattle shed,
  Where a mother laid her Baby
  In a manger for His bed:
  Mary was that mother mild,
  Jesus Christ her little Child.
 2. He came down to earth from heaven,
  Who is God and Lord of all,
  And His shelter was a stable,
  And His cradle was a stall;
  With the poor, and mean, and lowly,
  Lived on earth our Savior holy.
 3. And through all His wondrous childhood
  He would honor and obey,
  Love and watch the lowly maiden,
  In whose gentle arms He lay:
  Christian children all must be
  Mild, obedient, good as He.
 4. For he is our childhood’s pattern;
  Day by day, like us He grew;
  He was little, weak and helpless,
  Tears and smiles like us He knew;
  And He feeleth for our sadness,
  And He shareth in our gladness.
 5. And our eyes at last shall see Him,
  Through His own redeeming love;
  For that Child so dear and gentle
  Is our Lord in heaven above,
  And He leads His children on
  To the place where He is gone.
 6. Not in that poor lowly stable,
  With the oxen standing by,
  We shall see Him; but in heaven,
  Set at God’s right hand on high;
  Where like stars His children crowned
  All in white shall wait around

Text: Cecil Francis Humphreys
Music: Henry John Gauntlett

Leave a Reply