Yoruba Hymn: Wa, ẹnyin olootọ – O come, all ye faithful

1. Wa, ẹnyin olootọ, L’ayọ at’isẹgun,

Wa kalọ, wa kalọ sí Betlehem,

Wa ka lọ wo o! Ọba àwọn Angẹli

Ẹ wa kalọ juba Rẹ,

Ẹ wa kalọ juba Rẹ

Ẹ wa kalọ juba Kristi Oluwa.

2. Olodumare ni, Imọlẹ Ododo,

Ko si korira inu Wundia;

Ọlọrun papa ni, Ti abi, t’a ko da

Ẹ wa kalọ juba Rẹ,

Ẹ wa kalọ juba Rẹ

Ẹ wa kalọ juba Kristi Oluwa.

3. Angẹli ẹ kọrin, Kọrin itoye Rẹ,

Ki gbogbo ẹda orun si gbe’rin

Ogo f’Ọlọrun, L’oke orun lọhun

Ẹ wa kalọ juba Rẹ,

Ẹ wa kalọ juba Rẹ

Ẹ wa kalọ juba Kristi Oluwa.

English Version

1. O come, all ye faithful, joyful and triumphant,
O come ye, O come ye to Bethlehem!
Come, and behold Him, born the King of angels!

Refrain:
O come, let us adore Him;
O come, let us adore Him;
O come, let us adore Him, Christ, the Lord!


2. Sing, choirs of angels; sing in exultation;
sing, all ye citizens of heav’n above!
Glory to God, all glory in the highest!

[Refrain]


3. Yea, Lord, we greet Thee, born this happy morning;
Jesus, to Thee be all glory giv’n!
Word of the Father, now in flesh appearing!

[Refrain]

Author: John Francis Wade

Translator: Frederick Oakeley

Leave a Reply